27. Ó dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa, mo gbàgbọ́ pé ìwọ ni Mesaya Ọmọ Ọlọrun tí ó ń bọ̀ wá sí ayé.”
28. Nígbà tí Mata ti sọ báyìí tán, ó lọ pe Maria arabinrin rẹ̀ sí ìkọ̀kọ̀. Ó ní, “Olùkọ́ni ti dé, ó ń pè ọ́.”
29. Bí Maria ti gbọ́, ó dìde kíá, ó bá lọ sọ́dọ̀ Jesu.
30. (Jesu kò tíì wọ ìlú, ó wà ní ibi tí Mata ti pàdé rẹ̀.)
31. Nígbà tí àwọn Juu tí ó wà ninu ilé pẹlu Maria, tí wọn ń tù ú ninu, rí i pé ó sáré dìde, ó jáde, àwọn náà tẹ̀lé e, wọ́n ṣebí ó ń lọ sí ibojì láti lọ sunkún ni.
32. Nígbà tí Maria dé ibi tí Jesu wà, bí ó ti rí i, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Oluwa, ìbá jẹ́ pé o wà níhìn-ín, arakunrin mi kì bá tí kú.”
33. Nígbà tí Jesu rí i tí ó ń sunkún, tí àwọn Juu tí ó bá a jáde tún ń sunkún, orí rẹ̀ wú, ọkàn rẹ̀ wá bàjẹ́.
34. Ó bi wọ́n pé, “Níbo ni ẹ tẹ́ ẹ sí?”Wọ́n sọ fún un pé, “Oluwa, wá wò ó.”
35. Ni Jesu bá bú sẹ́kún.
36. Nígbà náà ni àwọn Juu sọ pé, “Ẹ ò rí i bí ó ti fẹ́ràn rẹ̀ tó!”
37. Àwọn kan ninu wọn ń sọ pé, “Ọkunrin yìí tí ó la ojú afọ́jú, ǹjẹ́ kò lè ṣe é kí ọkunrin yìí má fi kú?”