15. Apànìyàn ni ẹnikẹ́ni tí ó bá kórìíra arakunrin rẹ̀. Ẹ sì ti mọ̀ pé kò sí apànìyàn kan tí ìyè ainipẹkun ń gbé inú rẹ̀.
16. Ọ̀nà tí a fi mọ ìfẹ́ nìyí, pé ẹnìkan fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa. Nítorí náà, ó yẹ kí àwa náà fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún àwọn ará.
17. Bí ẹnìkan bá ní dúkìá ayé yìí, tí ó rí arakunrin rẹ̀ tí ó ṣe aláìní, tí kò ṣàánú rẹ̀, a ṣe lè wí pé ìfẹ́ Ọlọrun ń gbé inú irú ẹni bẹ́ẹ̀?
18. Ẹ̀yin ọmọde, ẹ má jẹ́ kí ìfẹ́ wa jẹ́ ti ọ̀rọ̀ ẹnu tabi ti ètè lásán; ṣugbọn kí ó jẹ́ ti ìwà ati ti òtítọ́.
19. Ọ̀nà tí a óo fi mọ̀ pé a jẹ́ ẹni òtítọ́ nìyí; níwájú Ọlọrun pàápàá ọkàn wa yóo balẹ̀.
20. Bí ọkàn wa bá tilẹ̀ dá wa lẹ́bi, kí á ranti pé Ọlọrun tóbi ju ọkàn wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.