Joẹli 1:17-20 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Irúgbìn díbàjẹ́ sinu ebè,àwọn ilé ìṣúra ti di ahoro,àwọn àká ti wó lulẹ̀,nítorí kò sí ọkà láti kó sinu wọn mọ́.

18. Àwọn ẹran ọ̀sìn ń kérora,àwọn agbo mààlúù dààmú,nítorí pé kò sí pápá oko fún wọn;àwọn agbo aguntan pàápàá dààmú.

19. Ìwọ ni mo kígbe pè, OLUWA,nítorí iná ti jó gbogbo pápá oko run,ó sì ti jó gbogbo igi oko run.

20. Àwọn ẹranko ìgbẹ́ pàápàá ń kígbe sí ọ, Ọlọrun,nítorí gbogbo àwọn odò ti gbẹ tán,àwọn pápá oko sì ti jóná.

Joẹli 1