Jobu 31:9-19 BIBELI MIMỌ (BM)

9. “Bí ọkàn mi bá fà sí obinrin olobinrin,tabi kí n máa pẹ́ kọ̀rọ̀ lẹ́nu ọ̀nà aládùúgbò mi;

10. jẹ́ kí iyawo mi máa se oúnjẹ fún ẹlòmíràn,kí ẹlòmíràn sì máa bá a lòpọ̀.

11. Nítorí ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó burú jù,ẹ̀ṣẹ̀ tí adájọ́ gbọdọ̀ jẹ mí níyà fún.

12. Iná ajónirun ni,tí yóo run gbogbo ohun ìní mi kanlẹ̀.

13. “Bí mo bá kọ̀ láti fetí sí ẹjọ́ àwọniranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin mi,nígbà tí wọ́n bá fẹ̀sùn kàn mí,

14. báwo ni n óo ṣe dúró níwájú Ọlọrun?Kí ni kí n wí nígbà tí ó bá bèèrè lọ́wọ́ mi?

15. Ṣebí ẹni tí ó dá mi ninu oyún,òun kan náà ló dá iranṣẹ mi?Òun ló mọ wá kí wọn tó bí wa.

16. “Bí mo bá fi ohunkohun pọ́n talaka lójú rí,tabi kí n fi opó sílẹ̀ ninu àìní,

17. tabi kí n dá oúnjẹ mi jẹ,láìfún ọmọ aláìníbaba jẹ

18. (láti ìgbà èwe rẹ̀ ni mo ti ń ṣe bíi baba fún un,tí mo sì ń tọ́jú rẹ̀ láti inú ìyá rẹ̀);

19. bí mo bá ti rí ẹni tí ó ń kú lọ,nítorí àìrí aṣọ bora,tabi talaka tí kò rí ẹ̀wù wọ̀,

Jobu 31