Jobu 11:7-18 BIBELI MIMỌ (BM)

7. “Ǹjẹ́ o lè wádìí àwọn ohun ìjìnlẹ̀ nípa Ọlọrun?Tabi kí o tọpinpin Olodumare?

8. Ó ga ju ọ̀run lọ, kí lo lè ṣe sí i?Ó jìn ju isà òkú lọ, kí lo lè mọ̀ nípa rẹ̀?

9. Ó gùn ju ayé lọ,Ó sì fẹ̀ ju òkun lọ.

10. Tí ó bá ń kọjá lọ, tí ó sì ti eniyan mọ́lé,tí ó pe olúwarẹ̀ lẹ́jọ́,ta ló lè yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò?

11. Nítorí ó mọ àwọn eniyan lásán,ṣé bí ó bá rí ẹ̀ṣẹ̀,kí ó má ṣe akiyesi rẹ̀?

12. Ó di ìgbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bá bí ọmọ rẹ̀ ní eniyan,kí òmùgọ̀ eniyan tó gbọ́n.

13. “Bí o bá fi ọkàn rẹ sí ohun tí ó tọ́,o óo lè nawọ́ sí i.

14. Bí o bá ń dẹ́ṣẹ̀, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́,má sì ṣe jẹ́ kí ìwà burúkú, wà ní ọwọ́ rẹ.

15. Nígbà náà ni o óo tó lè fi ìgboyà gbójú sókè láìlẹ́bi;o óo wà láìléwu,o kò sì ní bẹ̀rù.

16. O óo gbàgbé àwọn ìyọnu rẹ,nígbà tí o bá sì ranti rẹ̀,yóo dàbí ìkún omi tí ó ti wọ́ lọ.

17. Ayé rẹ yóo mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ;òkùnkùn rẹ yóo sì dàbí òwúrọ̀.

18. Ọkàn rẹ óo balẹ̀, nítorí pé o ní ìrètí,a óo dáàbò bò ọ́, o óo sì sinmi láìséwu.

Jobu 11