15. Nígbà náà ni o óo tó lè fi ìgboyà gbójú sókè láìlẹ́bi;o óo wà láìléwu,o kò sì ní bẹ̀rù.
16. O óo gbàgbé àwọn ìyọnu rẹ,nígbà tí o bá sì ranti rẹ̀,yóo dàbí ìkún omi tí ó ti wọ́ lọ.
17. Ayé rẹ yóo mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ;òkùnkùn rẹ yóo sì dàbí òwúrọ̀.
18. Ọkàn rẹ óo balẹ̀, nítorí pé o ní ìrètí,a óo dáàbò bò ọ́, o óo sì sinmi láìséwu.
19. O óo sùn, láìsí ìdágìrì,ọpọlọpọ eniyan ni wọn óo sì máa wá ojurere rẹ.