Jeremaya 9:13-22 BIBELI MIMỌ (BM)

13. OLUWA bá dáhùn, ó ní, “Nítorí pé wọ́n kọ òfin tí mo gbékalẹ̀ fún wọn sílẹ̀, wọn kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, wọn kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ mi,

14. ṣugbọn wọ́n ń fi agídí ṣe ìfẹ́ ọkàn wọn, wọ́n ń bọ àwọn oriṣa Baali, bí àwọn baba wọn ti kọ́ wọn.

15. Nítorí náà, n óo fún wọn ní igi tí ó korò jẹ, n óo sì fún wọn ní omi tí ó ní májèlé mu. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

16. N óo fọ́n wọn ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn ati àwọn baba ńlá wọn kò mọ̀, n óo sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá yọ idà tẹ̀lé wọn títí tí n óo fi pa wọ́n run.”

17. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní:“Ẹ ronú sí ọ̀rọ̀ yìí kí ẹ pe àwọn obinrin tíí máa ń ṣọ̀fọ̀ wá,ẹ ranṣẹ pe àwọn obinrin tí wọ́n mọ ẹkún sun dáradára;

18. kí wọ́n wá kíá,kí wọ́n wá máa sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lé wa lórí,kí omi sì máa dà lójú wa pòròpòrò.

19. Nítorí a gbọ́ tí ẹkún sọ ní Sioni,wọ́n ń ké pé, ‘A gbé!Ìtìjú ńlá dé bá wa,a níláti kó jáde nílé,nítorí pé àwọn ọ̀tá ti wó ilé wa.’ ”

20. Mo ní, “Ẹ̀yin obinrin, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí,ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀.Ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín obinrin ní ẹkún sísun,kí ẹ sì kọ́ aládùúgbò yín ní orin arò.

21. Nítorí ikú ti dé ojú fèrèsé wa,ó ti wọ ààfin wa.Ikú ń pa àwọn ọmọde nígboro,ati àwọn ọdọmọkunrin ní gbàgede.”

22. Sọ wí pé,“Òkú eniyan yóo sùn lọ nílẹ̀ bí ìgbọ̀nsẹ̀ lórí pápá tí ó tẹ́jú,ati bíi ìtí ọkà lẹ́yìn àwọn tí wọn ń kórè ọkà,kò sì ní sí ẹni tí yóo kó wọn jọ. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.”

Jeremaya 9