Jeremaya 9:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Orí mi ìbá jẹ́ kìkì omi,kí ojú mi sì jẹ́ orísun omijé;tọ̀sán-tòru ni ǹ bá fi máa sọkún,nítorí àwọn eniyan mi tí ogun ti pa.

2. Ìbá ṣe pé mo ní ilé èrò kan ninu aṣálẹ̀,ǹ bá kó àwọn eniyan mi dà sílẹ̀ níbẹ̀,ǹ bá sì kúrò lọ́dọ̀ wọn;nítorí alágbèrè ni gbogbo wọn,ati àgbájọ àwọn alárèékérekè eniyan.

3. Bí ẹni kẹ́ ọrun ni wọ́n kẹ́ ahọ́n wọn,láti máa fọ́n irọ́ jáde bí ẹni ta ọfà;dípò òtítọ́ irọ́ ní ń gbilẹ̀ ní ilẹ̀ náà.OLUWA ní,“Wọ́n ń tinú ibi bọ́ sinu ibi,wọn kò sì mọ̀ èmi OLUWA.”

4. Kí olukuluku ṣọ́ra lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀,kí ó má sì gbẹ́kẹ̀lé arakunrin rẹ̀ kankan.Nítorí pé ajinnilẹ́sẹ̀ ni gbogbo arakunrin,a-fọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ sì ni gbogbo aládùúgbò.

5. Olukuluku ń tan ọ̀rẹ́ rẹ̀ jẹ,kò sì sí ẹnìkan tí ń sọ òtítọ́.Wọ́n ti kọ́ ahọ́n wọn ní irọ́ pípa;wọ́n dẹ́ṣẹ̀ títí, ó sú wọn,wọn kò sì ronú àtipàwàdà.

6. Ìninilára ń gorí ìninilára,ẹ̀tàn ń gorí ẹ̀tàn,OLUWA ní, “Wọ́n kọ̀ wọn kò mọ̀ mí.”

7. Nítorí náà, ó ní:“Wò ó! N óo fọ̀ wọ́n mọ́,n óo dán wọn wò.Àbí, kí ni kí n tún ṣe fún àwọn eniyan yìí?

8. Ahọ́n wọn dàbí ọfà apanirun,wọ́n ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.Olukuluku ń sọ̀rọ̀ alaafia jáde lẹ́nu fún aládùúgbò rẹ̀,ṣugbọn ète ikú ni ó ń pa sí i ninu ọkàn rẹ̀.

9. Ṣé n kò wá ní jẹ wọ́n níyà fún àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe wọnyi?Àbí n kò ní gbẹ̀san ara mi lára irú orílẹ̀-èdè yìí?”

10. Mo ní, “Gbé ẹnu sókè kí o sọkún nítorí àwọn òkè ńlá,sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn nítorí àwọn pápá inú aṣálẹ̀,nítorí gbogbo wọn ti di ahoro, láìsí ẹnìkan tí yóo la ààrin wọn kọjá.A kò ní gbọ́ ohùn ẹran ọ̀sìn níbẹ̀.Ati ẹyẹ, ati ẹranko, gbogbo wọn ti sá lọ.”

Jeremaya 9