7. Wọ́n lu odi ìlú, àwọn ọmọ ogun sì gba ibẹ̀ sá jáde lóru. Wọ́n gba ẹnu ọ̀nà tí ó wà láàrin àwọn odi meji tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà ọba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Kalidea yí ìlú náà po, wọ́n bá dorí kọ apá ọ̀nà àfonífojì odò Jọdani.
8. Ṣugbọn àwọn ọmọ ogun Kalidea lépa ọba Sedekaya, wọ́n sì bá a ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko; gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bá fọ́nká lẹ́yìn rẹ̀.
9. Ọwọ́ àwọn ọmọ ogun Kalidea tẹ Sedekaya ọba, wọ́n sì mú un lọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila, ní ilẹ̀ Hamati, ọba Babiloni sì ṣe ìdájọ́ fún un.
10. Ọba Babiloni pa àwọn ọmọ Sedekaya lójú rẹ̀, ó sì pa àwọn ìjòyè Juda ní Ribila.
11. Ó yọ ojú Sedekaya mejeeji, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó mú un lọ sí Babiloni, ó sì jù ú sí ọgbà ẹ̀wọ̀n, títí tí ó fi kú.
12. Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù karun-un, ní ọdún kọkandinlogun tí Nebukadinesari ọba Babiloni jọba, Nebusaradani, olórí àwọn tí ń ṣọ́ ọba Babiloni, wọ ìlú Jerusalẹmu.
13. Ó sun ilé OLUWA níná ati ilé ọba ati gbogbo ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu; gbogbo àwọn ilé ńláńlá ní ó dáná sun.
14. Gbogbo àwọn ọmọ ogun Kalidea tí wọ́n wà pẹlu olórí àwọn tí ń ṣọ́ Nebukadinesari ọba wó gbogbo odi Jerusalẹmu lulẹ̀ patapata.
15. Nebusaradani, olórí àwọn olùṣọ́ ọba bá kó ninu àwọn talaka lẹ́rú pẹlu àwọn eniyan tí wọ́n kù ní ìlú, ati àwọn tí wọ́n ti sálọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni, ati àwọn oníṣẹ́-ọwọ́.