22. Ọpọ́n idẹ orí rẹ̀ ga ní igbọnwọ marun-un, wọ́n ṣe ẹ̀wọ̀n bí ẹ̀gbà ọrùn ati èso Pomegiranate yí ọpọ́n náà ká.
23. Òpó keji rí bákan náà pẹlu èso Pomegiranate. Mẹrindinlọgọrun-un ni àwọn èso Pomegiranate tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kọ̀ọ̀kan; ọgọrun-un ni gbogbo èso Pomegiranate tí ó wà ní àyíká ẹ̀wọ̀n náà.
24. Olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni mú Seraaya, olórí alufaa ati Sefanaya tí ó jẹ́ igbákejì rẹ̀ ati àwọn aṣọ́nà mẹtẹẹta.
25. Ó sì mú ọ̀gágun tí ń ṣe àkóso àwọn ọmọ ogun, ati meje ninu àwọn aṣojú ọba tí wọn rí láàrin ìlú ati akọ̀wé olórí ogun tí ń kọ orúkọ àwọn eniyan sílẹ̀ fún ogun jíjà. Wọ́n tún kó ọgọta eniyan ninu àwọn ará ìlú tí wọn rí láàrin ìgboro.
26. Nebusaradani olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba, kó wọn lọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila.
27. Ọba Babiloni sì pa wọ́n ní Ribila ní ilẹ̀ Hamati.Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe kó àwọn eniyan Juda ní ìgbèkùn kúrò ní ilẹ̀ wọn.
28. Iye àwọn eniyan tí Nebukadinesari kó lọ sí ìgbèkùn nìwọ̀nyí ní ọdún keje tí ó jọba, ó kó ẹgbẹẹdogun ó lé mẹtalelogun (3,023) lára àwọn Juu.
29. Ní ọdún kejidinlogun, ó kó àwọn ẹgbẹrin ó lé mejilelọgbọn (832) eniyan ní Jerusalẹmu.
30. Ní ọdún kẹtalelogun tí Nebukadinesari jọba, Nebusaradani, olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba, kó ojilelẹẹdẹgbẹrin ó lé marun-un (745) eniyan lára àwọn Juu. Gbogbo àwọn eniyan tí wọn kó lẹ́rú jẹ́ ẹgbaaji lé ẹgbẹta (4,600).
31. Ní ọdún kẹtadinlogoji lẹ́yìn tí a ti mú Jehoiakini, ọba Juda lọ sí ìgbèkùn, ní ọjọ́ kẹẹdọgbọn oṣù kejila ọdún náà Efilimerodaki, ọba Babiloni yẹ ọ̀rọ̀ Jehoiakini wò ní ọdún tí ó gorí oyè, ó sì pàṣẹ pé kí á tú u sílẹ̀ kúrò ní àtìmọ́lé.