36. Nítorí náà, OLUWA sọ fún àwọn ará Jerusalẹmu pé,“Ẹ wò ó, n óo gba ẹjọ́ yín rò,n óo sì ba yín gbẹ̀san.N óo jẹ́ kí omi òkun Babiloni gbẹ,n óo sì jẹ́ kí orísun odò rẹ̀ gbẹ.
37. Babiloni yóo sì di òkítì àlàpà, ati ibùgbé ajáko,yóo di ibi àríbẹ̀rù ati àrípòṣé, láìsí ẹnìkan kan ninu rẹ̀.
38. Gbogbo wọn yóo bú papọ̀ bíi kinniun,wọn yóo sì ké bí àwọn ọmọ kinniun.
39. Nígbà tí ara wọn bá gbóná,n óo se àsè kan fún wọn.N óo rọ wọ́n lọ́tí yó,títí tí wọn óo fi máa yọ ayọ̀ ẹ̀sín,tí wọn óo sì sùn lọ títí ayé.Wọn óo sùn, wọn kò sì ní jí mọ́.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
40. N óo fà wọ́n lọ sí ibi tí wọn tí ń pa ẹran,bí ọ̀dọ́ aguntan, ati àgbò ati òbúkọ.”
41. OLUWA ní,“Ẹ wò ó bí ogun ti kó Babiloni,Babiloni tí gbogbo ayé ń pọ́nlé!Ó wá di àríbẹ̀rù láàrin àwọn orílẹ̀-èdè!
42. Òkun ti ru bo Babiloni mọ́lẹ̀.Ìgbì òkun ti bò ó mọ́lẹ̀.
43. Àwọn ìlú rẹ̀ ti di àríbẹ̀rù,wọ́n ti di ilẹ̀ gbígbẹ ati aṣálẹ̀,ilẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbé mọ́,tí ọmọ eniyan kò sì gbà kọjá mọ́.
44. N óo fìyà jẹ oriṣa Bẹli ní Babiloni,n óo jẹ́ kí ó pọ ohun tí ó gbé mì.Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́,odi Babiloni pàápàá yóo wó lulẹ̀.