Jeremaya 50:17-23 BIBELI MIMỌ (BM)

17. OLUWA ní, “Israẹli dàbí aguntan tí àwọn kinniun ń lé kiri. Ọba Asiria ni ó kọ́kọ́ fi ṣe ẹran ìjẹ, ọba Babiloni sì ń wó àwọn egungun rẹ̀ tí ó kù.

18. Nítorí náà èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, ni mo sọ pé n óo jẹ ọba Babiloni ati ilẹ̀ rẹ̀ níyà, bí mo ṣe jẹ ọba Asiria níyà.

19. N óo mú Israẹli pada sí ibùjẹ rẹ̀, yóo máa jẹ oúnjẹ tí ó bá hù lórí òkè Kamẹli ati ní agbègbè Baṣani, yóo sì tẹ́ ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn lórí òkè Efuraimu ati òkè Gileadi.

20. OLUWA ní, Nígbà tí ó bá yá, tí àkókò bá tó, a óo wá ẹ̀ṣẹ̀ tì ní Israẹli ati Juda; nítorí pé n óo dáríjì àwọn tí mo bá ṣẹ́kù.”

21. OLUWA ní,“Ẹ gbógun ti ilẹ̀ Merataimu, ati àwọn ará Pekodi.Ẹ pa wọ́n, kí ẹ sì run wọ́n patapata.Gbogbo nǹkan tí mo pàṣẹ fun yín ni kí ẹ ṣe.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

22. A gbọ́ ariwo ogun ati ìparun ńlá, ní ilẹ̀ náà.

23. Ẹ wo bí a ti gé òòlù tó ti ń lu gbogbo ayé lulẹ̀,tí a sì fọ́ ọ!Ẹ wo bí Babiloni ti di ohun àríbẹ̀rù, láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.

Jeremaya 50