Jeremaya 5:11-17 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Nítorí pé ilé Israẹli ati ilé Juda ti ṣe alaiṣootọ sí mi.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

12. Àwọn eniyan yìí ti sọ ọ̀rọ̀ èké nípa OLUWA,wọ́n ní, “OLUWA kọ́! Kò ní ṣe nǹkankan;ibi kankan kò ní dé bá wa,bẹ́ẹ̀ ni a kò ní rí ogun tabi ìyàn.”

13. Àwọn wolii yóo di àgbá òfo;nítorí kò sí ọ̀rọ̀ OLUWA ninu wọn.Bí wọ́n ti wí ni ọ̀rọ̀ yóo rí fún wọn.

14. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní,“Nítorí ohun tí wọ́n sọ yìí,wò ó, n óo jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi di iná lẹ́nu rẹ.N óo sì jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi dàbí igi,iná yóo sì jó wọn run.

15. Ẹ wò ó, ẹ̀yin ọmọ ilé Israẹli,mò ń mú orílẹ̀-èdè kan bọ̀ wá ba yín, láti ilẹ̀ òkèèrè,tí yóo ba yín jà.Láti ayé àtijọ́ ni orílẹ̀-èdè ọ̀hún ti wà,orílẹ̀-èdè alágbára ni.Ẹ kò gbọ́ èdè wọn,ẹ kò sì ní mọ ohun tí wọ́n ń sọ.

16. Apó ọfà wọn dàbí isà òkú tó yanu sílẹ̀,alágbára jagunjagun ni gbogbo wọn.

17. Wọn yóo jẹ yín ní oúnjẹ,wọn yóo sì kó gbogbo ìkórè oko yín lọ,wọn yóo run àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin.Wọn yóo run ẹran ọ̀sìn yín,ati àwọn mààlúù yín.Wọn yóo run èso ọgbà àjàrà yín, ati igi ọ̀pọ̀tọ́ yín.Idà ni wọn yóo fi pa àwọn ìlú olódi yín tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé run.”

Jeremaya 5