18. Sọ̀kalẹ̀ kúrò ninu ògo rẹ, kí o jókòó lórí ìyàngbẹ ilẹ̀, ìwọ tí ò ń gbé Diboni!Nítorí pé ẹni tí óo pa Moabu run ti dojú kọ ọ́,ó sì ti wó àwọn ibi ààbò rẹ̀.
19. Dúró lẹ́bàá ọ̀nà kí o máa ṣọ́nà, ìwọ tí ò ń gbé Aroeri!Bèèrè lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n sálọ; bi àwọn tí ń sá àsálà pé, ‘Kí ló ṣẹlẹ̀?’
20. Ìtìjú ti bá Moabu, nítorí pé ó ti wó lulẹ̀; ẹ kígbe, ẹ máa sọkún.Ẹ kéde rẹ̀ ní ipadò Anoni, pé,‘Moabu ti parẹ́, ó ti di òkítì àlàpà.’
21. “Ìdájọ́ ti dé sórí àwọn ìlú tí ó wà ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú: Holoni, Jahisai, ati Mefaati;
22. Diboni, Nebo, ati Beti Dibilataimu,
23. Kiriataimu, Betigamuli, ati Betimeoni,
24. Kerioti, Bosira, ati gbogbo àwọn ìlú ilẹ̀ Moabu, ati àwọn tí wọ́n wà nítòsí, ati àwọn tí wọ́n wà lókèèrè.
25. Ipá Moabu ti pin, a sì ti ṣẹ́ ẹ lápá. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
26. OLUWA ní,“Ẹ rọ Moabu lọ́tí yó,nítorí pé ó gbéraga sí OLUWA;kí ó lè máa yíràá ninu èébì rẹ̀,a óo sì fi òun náà ṣẹ̀sín.
27. Moabu, ṣebí ò ń fi Israẹli ṣe yẹ̀yẹ́?Ṣé o bá a láàrin àwọn ọlọ́ṣà ni,tí ó fi jẹ́ pé nígbàkúùgbà tí o bá ń sọ̀rọ̀ rẹ̀, ń ṣe ni o máa ń mi orí rẹ?
28. “Ẹ fi ààrin ìlú sílẹ̀, kí ẹ lọ máa gbé inú àpáta, ẹ̀yin ará Moabu!Ẹ ṣe bí àdàbà, tí ó kọ́lé rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ẹnu ihò àpáta.
29. A ti gbọ́ nípa ìgbéraga Moabu,ó ní ìgbéraga lọpọlọpọ,a ti gbọ́ nípa èrò gíga rẹ̀, ati ìgbéraga rẹ̀,nípa àfojúdi rẹ̀, ati nípa ìwà ìjọra-ẹni-lójú rẹ̀.
30. Mo mọ̀ pé aláfojúdi ni.Ó ń fọ́nnu lásán ni, kò lè ṣe nǹkankan tó yanjú.
31. Nítorí náà, ni mo ṣe ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, tí mò ń kígbe sókè nítorí Moabutí mo sì ń ṣọ̀fọ̀ nítorí àwọn ará Kiri Heresi.
32. Ìwọ ọgbà àjàrà Sibima,ọ̀rọ̀ rẹ pa mí lẹ́kún, ju ti Jaseri lọ!Àwọn ẹ̀ka rẹ tàn dé òkun, wọ́n tàn títí dé Jaseri,apanirun sì ti kọlu àwọn èso ẹ̀ẹ̀rùn rẹ, ati èso àjàrà rẹ.