Jeremaya 46:5-9 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Oluwa ní, “Kí ni mo rí yìí?Ẹ̀rù ń bà wọ́n, wọ́n sì ń pada sẹ́yìn.A ti lu àwọn ọmọ ogun wọn bolẹ̀,wọ́n sì ń sálọ pẹlu ìkánjú;wọn kò bojú wẹ̀yìn, ìpayà yí wọn ká!

6. Àwọn tí ẹsẹ̀ wọn yá nílẹ̀ kò lè sálọ,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ogun kò lè sá àsálà.Ìhà àríwá, lẹ́bàá odò Yufurate, ni wọ́n tí fẹsẹ̀ kọ, tí wọ́n sì ṣubú.

7. Ta ló ń ru bí odò Naili yìí,bí odò tí ó kún bo bèbè rẹ̀?

8. Ijipti ń ru bí odò Naili,bí odò tí ó kún bo bèbè rẹ̀.Ijipti wí pé, ‘N óo kún, n óo sì bo ayé mọ́lẹ̀,n óo pa àwọn ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú wọn run.

9. Ó yá, ẹṣin, ẹ gbéra,kí kẹ̀kẹ́ ogun máa sáré kíkankíkan!Kí àwọn ọmọ ogun máa nìṣó,àwọn ọmọ ogun Etiopia ati Puti, tí wọ́n mọ asà á lò,àwọn ọmọ ogun Ludi, tí wọ́n mọ ọfà á ta dáradára.’ ”

Jeremaya 46