4. Nisinsinyii, wò ó, mo tú ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ ọwọ́ rẹ sílẹ̀, bí o bá fẹ́ bá mi lọ sí Babiloni, máa bá mi kálọ, n óo tọ́jú rẹ dáradára; bí o kò bá sì fẹ́ lọ, dúró. Wò ó, gbogbo ilẹ̀ nìyí níwájú rẹ yìí, ibi tí o bá fẹ́ tí ó dára lójú rẹ ni kí o lọ.
5. Bí o bá fẹ́ pada, pada lọ bá Gedalaya ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ẹni tí ọba Babiloni fi ṣe gomina àwọn ìlú Juda, kí o máa bá a gbé láàrin àwọn eniyan náà. Bí o kò bá sì fẹ́ bẹ́ẹ̀, ibi tí ó bá wù ọ́ láti lọ ni kí o lọ.” Olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba bá fún un ní owó, oúnjẹ, ati ẹ̀bùn, ó ní kí ó máa lọ.
6. Jeremaya bá pada sọ́dọ̀ Gedalaya, ọmọ Ahikamu ní Misipa, ó sì ń gbé pẹlu rẹ̀ láàrin àwọn eniyan tí wọn kù ní ilẹ̀ náà.
7. Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà ní ìgbèríko pẹlu àwọn ọmọ ogun wọn gbọ́ pé ọba Babiloni ti fi Gedalaya ọmọ Ahikamu jẹ gomina ní ilẹ̀ Juda, ati pé ó ti fi ṣe olùtọ́jú àwọn ọkunrin, ati àwọn obinrin, ati àwọn ọmọde ati díẹ̀ ninu àwọn talaka ilẹ̀ Juda, tí wọn kò kó lọ sí Babiloni,
8. wọ́n lọ bá Gedalaya ní Misipa. Àwọn tí wọ́n lọ nìwọ̀nyí: Iṣimaeli, ọmọ Netanaya, Johanani, ọmọ Karea, Seraaya, ọmọ Tanhumeti, àwọn ọmọ Efai, ará Netofa, Jesanaya, ọmọ ará Maakati, àwọn àtàwọn eniyan wọn.
9. Gedalaya bá búra fún àwọn ati àwọn eniyan wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù ati sin àwọn ará Kalidea. Ẹ máa gbé ilẹ̀ yìí, kí ẹ máa sin ọba Babiloni, yóo sì dára fun yín.
10. Ní tèmi, Misipa ni n óo máa gbé kí n lè máa rí ààyè bá àwọn ará Kalidea tí wọn wá dótì wá sọ̀rọ̀. Ẹ̀yin ẹ máa kó ọtí, èso, ati òróró jọ sinu ìkòkò yín, kí ẹ sì máa gbé àwọn ìlú tí ẹ ti gbà.”