23. Mo bojú wo ilé ayé, ilé ayé ṣófo,ó rí júujùu;mo ṣíjú wo ojú ọ̀run,kò sí ìmọ́lẹ̀ níbẹ̀.
24. Mo wo àwọn òkè ńlá, wọ́n ń mì tìtì,gbogbo òkè kéékèèké ń sún lọ síhìn-ín sọ́hùn-ún.
25. Mo wò yíká, n kò rí ẹnìkan,gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ti fò sálọ.
26. Mo wò yíká, mo rí i pé gbogbo ilẹ̀ ọlọ́ràá ti di aṣálẹ̀,gbogbo ìlú sì ti di òkítì àlàpà níwájú OLUWA,nítorí ibinu ńlá rẹ̀.
27. Nítorí OLUWA ti sọ pé,gbogbo ilẹ̀ náà yóo di ahoro;sibẹ òpin kò ní tíì dé.