1. OLUWA ní, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, bí ẹ bá fẹ́ yipada, ọ̀dọ̀ mi ni kí ẹ pada sí. Mo kórìíra ìbọ̀rìṣà; nítorí náà bí ẹ bá jáwọ́ ninu rẹ̀, tí ẹ kò bá ṣìnà kiri mọ́,
2. tí ẹ bá ń búra pẹlu òtítọ́ pé, ‘Bí OLUWA ti wà láàyè,’ lórí ẹ̀tọ́ ati òdodo, àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóo máa fi orúkọ mi súre fún ara wọn, wọn yóo sì máa ṣògo ninu mi.”
3. Nítorí pé OLUWA sọ fún àwọn ará Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu pé, “Ẹ tún oko yín tí ẹ ti patì tẹ́lẹ̀ kọ, ẹ má sì gbin èso sáàrin ẹ̀gún.
4. Ẹ kọ ara yín ní ilà abẹ́ fún OLUWA, kí ẹ sì kọ ara yín ní ilà ọkàn, ẹ̀yin ará Juda ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu; kí ibinu mi má baà dé, bí iná tí ó ń jó tí kò sí ẹni tí ó lè pa á, nítorí iṣẹ́ ibi yín.”
5. Ẹ sọ ọ́ ní Juda,ẹ sì kéde rẹ̀ láàrin Jerusalẹmu pé,“Ẹ fọn fèrè káàkiri ilẹ̀ náà,kí ẹ sì kígbe sókè pé,‘Ẹ kó ara yín jọ kí á lọ sí àwọn ìlú olódi.’
6. Ẹ gbé àsíá sókè sí Sioni,pé kí wọn sá àsálà, kí wọn má ṣe dúró,nítorí mò ń mú ibi ati ìparun ńlá bọ̀ láti ìhà àríwá.