Jeremaya 4:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA ní, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, bí ẹ bá fẹ́ yipada, ọ̀dọ̀ mi ni kí ẹ pada sí. Mo kórìíra ìbọ̀rìṣà; nítorí náà bí ẹ bá jáwọ́ ninu rẹ̀, tí ẹ kò bá ṣìnà kiri mọ́,

2. tí ẹ bá ń búra pẹlu òtítọ́ pé, ‘Bí OLUWA ti wà láàyè,’ lórí ẹ̀tọ́ ati òdodo, àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóo máa fi orúkọ mi súre fún ara wọn, wọn yóo sì máa ṣògo ninu mi.”

3. Nítorí pé OLUWA sọ fún àwọn ará Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu pé, “Ẹ tún oko yín tí ẹ ti patì tẹ́lẹ̀ kọ, ẹ má sì gbin èso sáàrin ẹ̀gún.

4. Ẹ kọ ara yín ní ilà abẹ́ fún OLUWA, kí ẹ sì kọ ara yín ní ilà ọkàn, ẹ̀yin ará Juda ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu; kí ibinu mi má baà dé, bí iná tí ó ń jó tí kò sí ẹni tí ó lè pa á, nítorí iṣẹ́ ibi yín.”

5. Ẹ sọ ọ́ ní Juda,ẹ sì kéde rẹ̀ láàrin Jerusalẹmu pé,“Ẹ fọn fèrè káàkiri ilẹ̀ náà,kí ẹ sì kígbe sókè pé,‘Ẹ kó ara yín jọ kí á lọ sí àwọn ìlú olódi.’

6. Ẹ gbé àsíá sókè sí Sioni,pé kí wọn sá àsálà, kí wọn má ṣe dúró,nítorí mò ń mú ibi ati ìparun ńlá bọ̀ láti ìhà àríwá.

7. Kinniun kan ti jáde lọ láti inú igbó tí ó wà;ọ̀kan ninu àwọn tí wọ́n máa ń run àwọn orílẹ̀-èdè ti gbéra;ó ti jáde kúrò ní ipò rẹ̀,láti sọ ilẹ̀ yín di ahoro.Yóo pa àwọn ìlú yín run,kò sì ní sí eniyan ninu wọn mọ́.

8. Nítorí èyí, ẹ fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora,ẹ sọkún kí ẹ máa ké tẹ̀dùntẹ̀dùn,nítorí ìrúnú gbígbóná OLUWAkò tíì yipada kúrò lọ́dọ̀ wa.”

9. OLUWA ní, “Tó bá di ìgbà náà, ojora yóo mú ọba ati àwọn ìjòyè, àwọn alufaa yóo dààmú, ẹnu yóo ya àwọn wolii.”

10. Mo bá dáhùn pé, “Háà, OLUWA Ọlọrun, àṣé ò ń tan àwọn eniyan wọnyi, ati àwọn ará Jerusalẹmu ni, nígbà tí o sọ fún wọn pé, yóo dára fún wọn; àṣé idà ti dé ọrùn wọn!”

11. A óo wí fún àwọn eniyan yìí, ati àwọn ará Jerusalẹmu ní ìgbà náà pé afẹ́fẹ́ gbígbóná kan ń fẹ́ bọ̀ láti orí àwọn òkè, ninu pápá, ó ń fẹ́ bọ̀ sọ́dọ̀ àwọn eniyan mi; kì í ṣe afẹ́fẹ́ lásán tíí fẹ́ pàǹtí ati ìdọ̀tí dànù.

Jeremaya 4