Jeremaya 38:24-28 BIBELI MIMỌ (BM)

24. Sedekaya ọba bá kìlọ̀ fún Jeremaya pé, “Má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ gbogbo nǹkan tí a jọ sọ, o kò sì ní kú.

25. Bí àwọn ìjòyè bá gbọ́ pé a jọ sọ̀rọ̀, bí wọn bá wá sọ́dọ̀ rẹ tí wọn ní kí o sọ nǹkan tí o bá mi sọ fún àwọn, ati èsì tí mo fún ọ, tí wọn bẹ̀ ọ́ pé kí o má fi ohunkohun pamọ́ fún àwọn, tí wọn sì ṣe ìlérí pé àwọn kò ní pa ọ́,

26. sọ fún wọn pé ẹ̀bẹ̀ ni ò ń bẹ̀ mí pé kí n má dá ọ pada sí ilé Jonatani; kí o má baà kú sibẹ.”

27. Gbogbo àwọn ìjòyè tọ Jeremaya lọ, wọ́n bí í, ó sì fún wọn lésì gẹ́gẹ́ bí ọba tí pàṣẹ fún un. Wọ́n bá dákẹ́, nítorí ẹnikẹ́ni kò gbọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n jọ sọ.

28. Jeremaya bá ń gbé gbọ̀ngàn àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin títí di ọjọ́ tí ogun kó Jerusalẹmu.

Jeremaya 38