1. Nebukadinesari, ọba Babiloni fi Sedekaya, ọmọ Josaya, jọba ní ilẹ̀ Juda dípò Jehoiakini, ọmọ Jehoiakimu.
2. Ṣugbọn Sedekaya ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ati àwọn eniyan náà kò pa ọ̀rọ̀ tí OLUWA ní kí Jeremaya wolii sọ fún wọn mọ́.
3. Ọba Sedekaya rán Jehukali, ọmọ Ṣelemaya, ati Sefanaya, alufaa, ọmọ Maaseaya, sí Jeremaya wolii, pé kí ó jọ̀wọ́ bá àwọn gba adura sí OLUWA Ọlọrun.
4. Ní àkókò yìí Jeremaya sì ń rìn káàkiri láàrin àwọn eniyan, nítorí wọn kò tíì jù ú sẹ́wọ̀n nígbà náà.
5. Àwọn ọmọ ogun Farao ti jáde, wọ́n ń bọ̀ láti Ijipti; nígbà tí àwọn ará Kalidea tí wọn dóti Jerusalẹmu gbọ́ pé wọ́n ń bọ̀, wọ́n kúrò ní Jerusalẹmu.