Jeremaya 3:3-10 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Nítorí náà ni òjò kò ṣe rọ̀,tí òjò àkọ́rọ̀ kò rọ̀ ní àkókò tí ó yẹ.Sibẹsibẹ, ẹ̀ ń gbéjú gbéré bí aṣẹ́wó,ojú kò sì tì yín.

4. Israẹli, o wá ń pè mí nisinsinyii, ò ń sọ pé,‘Ìwọ ni baba mi, ìwọ ni ọ̀rẹ́ mi láti ìgbà èwe mi.

5. Ṣé o kò ní dáwọ́ ibinu rẹ dúró ni?Tabi títí ayé ni o óo fi máa bínú?’Lóòótọ́ o ti sọ bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀,ṣugbọn o ti ṣe ìwọ̀n ibi tí o lè ṣe.”

6. OLUWA sọ fún mi ní ìgbà ayé ọba Josaya pé: “Ṣé o rí ohun tí Israẹli, alaiṣootọ ẹ̀dá ṣe? Ṣé o rí i bí ó tí ń lọ ṣe àgbèrè lórí gbogbo òkè ati lábẹ́ gbogbo igi tútù?

7. Mo rò pé yóo pada tọ̀ mí wá, lẹ́yìn tí ó bá ṣe àgbèrè rẹ̀ tán ni; ṣugbọn kò pada; Juda arabinrin rẹ̀, alaiṣootọ sì rí i,

8. ó mọ̀ pé nítorí ìwà àgbèrè Israẹli, alaiṣootọ, ni mo ṣe lé e jáde, tí mo sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Sibẹsibẹ Juda tí òun pàápàá jẹ́ alaiṣootọ, kò bẹ̀rù, òun náà lọ ṣe àgbèrè.

9. Nítorí pé ìwà àgbèrè jẹ́ nǹkan kékeré lójú rẹ̀, ó ṣe àgbèrè pẹlu òkúta ati igi ó sì ba ilẹ̀ náà jẹ́.

10. Sibẹsibẹ, lẹ́yìn gbogbo èyí, Juda arabinrin rẹ̀, ọ̀dàlẹ̀, kò fi tọkàntọkàn pada tọ̀ mí wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ojú ayé ni wọ́n ń ṣe. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Jeremaya 3