22. Ṣugbọn ọba Jehoiakimu rán Elinatani, ọmọ Akibori, ati àwọn ọkunrin kan lọ sí Ijipti,
23. wọ́n mú Uraya jáde ní ilẹ̀ Ijipti, wọ́n mú un tọ ọba Jehoiakimu wá. Ọba Jehoiakimu fi idà pa á, ó sì ju òkú rẹ̀ sí ibi tí wọn ń sin àwọn talaka sí.
24. Ṣugbọn Ahikamu ọmọ Ṣafani fọwọ́ sí ọ̀rọ̀ mi, kò sì jẹ́ kí á fà mí lé àwọn eniyan lọ́wọ́ láti pa.