23. “Ṣé nítòsí nìkan ni mo ti jẹ́ Ọlọrun ni, èmi kì í ṣe Ọlọrun ọ̀nà jíjìn?
24. Ǹjẹ́ ẹnìkan lè sápamọ́ sí ìkọ̀kọ̀ kan tí n kò fi ní rí i? Kì í ṣe èmi ni mo wà ní gbogbo ọ̀run tí mo sì tún wà ní gbogbo ayé?
25. Mo gbọ́ ohun tí àwọn wolii tí wọn ń fi orúkọ mi sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ń sọ, tí wọn ń sọ pé, àwọn lá àlá, àwọn lá àlá!
26. Irọ́ yóo ti pẹ́ tó lọ́kàn àwọn wolii èké tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn.
27. Wọ́n ṣebí àwọn lè fi àlá tí olukuluku wọn ń rọ́ fún ẹnìkejì rẹ̀ mú àwọn eniyan mi gbàgbé orúkọ mi, bí àwọn baba wọn ṣe gbàgbé mi, tí wọn ń tẹ̀lé oriṣa Baali.
28. Kí àwọn wolii tí wọn lá àlá máa rọ́ àlá wọn, ṣugbọn ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí ó sọ ọ́ pẹlu òtítọ́. Báwo ni a ṣe lè fi ìyàngbò wé ọkà?
29. Ṣebí bí iná ni ọ̀rọ̀ mi rí, ati bí òòlù irin tíí fọ́ àpáta sí wẹ́wẹ́?