1. Nígbà tí Paṣuri alufaa, ọmọ Imeri, tí ó jẹ́ olórí àwọn olùṣọ́ ilé OLUWA, gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Jeremaya ń sọ,
2. ó ní kí wọn lu Jeremaya, kí wọn kàn ààbà mọ́ ọn lẹ́sẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà Bẹnjamini ti òkè, ní ilé OLUWA.
3. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, nígbà tí Paṣuri tú Jeremaya sílẹ̀ ninu ààbà, Jeremaya wí fún un pé, “Kì í ṣe Paṣuri ni OLUWA pe orúkọ rẹ, ìpayà lọ́tùn-ún ati lósì ni OLUWA pè ọ́.
4. OLUWA ní, ‘N óo sọ ọ́ di ìpayà fún ara rẹ ati fún gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ràn rẹ. Àwọn ọ̀tá yóo fi idà pa wọ́n níṣojú rẹ, n óo fi gbogbo ilẹ̀ Juda lé ọba Babiloni lọ́wọ́. Yóo kó wọn ní ìgbèkùn lọ sí Babiloni, yóo sì fi idà pa wọ́n.
5. Bákan náà, n óo da gbogbo ọrọ̀ ìlú yìí, ati gbogbo èrè iṣẹ́ tí wọ́n ṣe lé àwọn ará Babiloni lọ́wọ́, pẹlu gbogbo nǹkan olówó iyebíye wọn, ati gbogbo ìṣúra àwọn ọba Juda; gbogbo rẹ̀ ni àwọn ọ̀tá wọn, àwọn ará Babiloni yóo fogun kó, wọn yóo sì rù wọ́n lọ sí Babiloni.