13. OLUWA wí pé, “Nítorí pé àwọn eniyan mi ṣe nǹkan burúkú meji:wọ́n ti kọ èmi orísun omi ìyè sílẹ̀,wọ́n ṣe kànga fún ara wọn;kànga tí ó ti là, tí kò lè gba omi dúró.
14. “Ṣé ẹrú ni Israẹli ni,àbí ọmọ ẹrú tí ẹrú bí sinu ilé?Báwo ló ṣe wá di ìjẹ fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.
15. Àwọn kinniun ti bú mọ́ ọn,wọ́n bú ramúramù.Wọ́n sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ahoro.Àwọn ìlú rẹ̀ sì ti tú, wọ́n ti wó palẹ̀,láìsí eniyan tí ń gbé inú wọn.
16. Bákan náà, àwọn ará Memfisi ati Tapanhesi ti fọ́ adé orí rẹ̀.
17. Ṣebí ọwọ́ ara yín ni ẹ fi fà á sí orí ara yín,nígbà tí ẹ̀yin kọ Ọlọrun yín sílẹ̀,nígbà tí ó ń tọ yín sọ́nà?
18. Kí ni èrè tí ẹ rí nígbà tí ẹ lọ sí Ijipti,tí ẹ lọ mu omi odò Naili,àbí kí ni èrè tí ẹ gbà bọ̀ nígbà tí ẹ lọ sí Asiria,tí ẹ lọ mu omi odò Yufurate.
19. Ìwà burúkú yín yóo fìyà jẹ yín,ìpadà sẹ́yìn yín yóo sì kọ yín lọ́gbọ́n.Kí ó da yín lójú pé,nǹkan burúkú ni, ìgbẹ̀yìn rẹ̀ kò sì ní dùn,pé ẹ fi èmi OLUWA Ọlọrun yín sílẹ̀;ìbẹ̀rù mi kò sí ninu yín.Èmi, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
20. OLUWA wí pé,“Nítorí pé ó ti pẹ́ tí ẹ ti bọ́ àjàgà yín,tí ẹ sì ti tú ìdè yín;tí ẹ sọ pé, ẹ kò ní sìn mí.Ẹ̀ ń lọ káàkiri lórí gbogbo òkè,ati lábẹ́ gbogbo igi tútù;ẹ̀ ń foríbalẹ̀, ẹ̀ ń ṣe bíi panṣaga.
21. Sibẹ mo gbìn yín gẹ́gẹ́ bí àjàrà tí mo fẹ́,tí èso rẹ̀ dára.Báwo ni ẹ ṣe wá yipada patapata,tí ẹ di àjàrà igbó tí kò wúlò?
22. Bí ẹ tilẹ̀ fi eérú fọ ara yín,tí ẹ sì fi ọpọlọpọ ọṣẹ wẹ̀,sibẹ, àbààwọ́n ẹ̀bi yín wà níwájú mi.
23. Báwo ní ẹ ṣe lè wí pé ẹ kì í ṣe aláìmọ́;ati pé ẹ kò tẹ̀lé àwọn oriṣa Baali?Ẹ wo irú ìwà tí ẹ hù ninu àfonífojì,kí ẹ ranti gbogbo ibi tí ẹ ṣebí ọmọ ràkúnmí tí ń lọ, tí ń bọ̀;tí ń tọ ipa ọ̀nà ara rẹ̀.
24. Ẹ dàbíi Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́, tí aṣálẹ̀ ti mọ́ lára,tí ń ṣí imú kiri,nígbà tí ó ń wa akọ tí yóo gùn ún.Ta ló lè dá a dúró?Kí akọ tí ó bá ń wá amá wulẹ̀ ṣe ara rẹ̀ ní wahala,nítorí yóo yọjú nígbà tí àkókò gígùn rẹ̀ bá tó.
25. Má rìn láìwọ bàtà, Israẹli,má sì jẹ́ kí òùngbẹ gbẹ ọ́.Ṣugbọn o sọ pé, ‘Kò sí ìrètí,nítorí àjèjì oriṣa ni mo fẹ́,n óo sì wá wọn kiri.’ ”
26. OLUWA ní, “Bí ojú tíí ti olè nígbà tí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́,bẹ́ẹ̀ ni ojú yóo tì yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.Àtẹ̀yin ati àwọn ọba yín, ati àwọn ìjòyè yín,ati àwọn alufaa yín, ati àwọn wolii yín;
27. ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wí fún igi pé igi ni baba yín,tí ẹ sì ń sọ fún òkúta pé òkúta ni ó bi yín;nítorí pé dípò kí ẹ kọjú sí ọ̀dọ̀ mi,ẹ̀yìn ni ẹ kọ sí mi.Ṣugbọn nígbà tí ìṣòro dé ba yín,ẹ bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pè mí pé kí n dìde, kí n gbà yín là.
28. “Ṣugbọn níbo ni àwọn oriṣa yín tí ẹ dá fún ara yín wà?Kí wọn dìde, tí wọ́n bá lè gbà yín ní àkókò ìṣòro yín!Ṣebí bí ìlú yín ti pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni àwọn oriṣa yín náà pọ̀ tó, ẹ̀yin ará Juda.