1. OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:
2. “O kò gbọdọ̀ fẹ́ iyawo tabi kí o bímọ ní ibí yìí.
3. Nítorí ohun tí OLUWA sọ nípa àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin tí a bí ní ibí yìí, ati nípa ìyá tí ó bí wọn, ati baba tí a bí wọn fún ni pé,
4. àìsàn burúkú ni yóo pa wọ́n. Ẹnìkan kò ní ṣọ̀fọ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní sin wọ́n; bí ìgbọ̀nsẹ̀ ni wọn yóo rí lórí ilẹ̀. Ogun ati ìyàn ni yóo pa wọ́n run, òkú wọn yóo sì di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko.