6. Lẹ́yìn ọpọlọpọ ọjọ́, OLUWA sọ fún mi pé, “Dìde, lọ sí odò Yufurate kí o mú aṣọ tí mo ní kí o fi pamọ́ sibẹ wá.”
7. Mo bá lọ sí ẹ̀bá odò Yufurate; mo gbẹ́ ilẹ̀, mo yọ aṣọ funfun náà jáde kúrò ní ibi tí mo bò ó mọ́. Ó ti bàjẹ́; kò sì wúlò fún ohunkohun mọ́.
8. OLUWA sọ fún mi pé,
9. “Bẹ́ẹ̀ gan-an ni n óo ṣe sọ ògo Juda ati ti Jerusalẹmu di ìbàjẹ́.
10. Àwọn ẹni ibi wọnyi, tí wọ́n kọ̀, tí wọn kò gbọ́ tèmi, tí wọn ń fi oríkunkun tẹ̀lé ìfẹ́ ọkàn wọn, tí wọ́n sì ti sá tọ àwọn oriṣa lọ, tí wọn ń sìn wọ́n, tí wọn sì ń bọ wọ́n. Wọn yóo dàbí aṣọ yìí tí kò wúlò fún ohunkohun.
11. Bí aṣọ ìlọ́dìí tií lẹ̀ mọ́ ọkunrin lára, bẹ́ẹ̀ ni mo mú kí gbogbo ilé Israẹli ati gbogbo ilé Juda súnmọ́ mi, kí wọ́n lè jẹ́ eniyan mi, ati orúkọ mi, ìyìn mi, ati ògo mi. Ṣugbọn wọ́n kọ̀, wọn kò gbọ́.”
12. OLUWA ní, “Sọ fún wọn pé, èmi OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, ‘Gbogbo ìkòkò ni a óo rọ ọtí waini kún.’ Wọn yóo dá ọ lóhùn pé, ‘Ṣé a kò mọ̀ pé gbogbo ìkòkò ni a óo rọ ọtí waini kún ni?’