15. n óo ranti majẹmu tí mo bá ẹ̀yin ati gbogbo ẹ̀dá alààyè dá pé, omi kò ní kún débi pé yóo pa ayé rẹ́ mọ́.
16. Nígbà tí òṣùmàrè bá yọ, n óo wò ó, n óo sì ranti majẹmu ayérayé tí èmi Ọlọrun bá gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà láyé dá.
17. Èyí ni majẹmu tí mo bá gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà láyé dá.”
18. Àwọn ọmọ Noa tí wọ́n jáde ninu ọkọ̀ ni: Ṣemu, Hamu ati Jafẹti. Hamu ni ó bí Kenaani.
19. Àwọn ọmọ Noa mẹtẹẹta yìí ni baba ńlá gbogbo ayé.
20. Noa ni ẹni kinni tí ó kọ́kọ́ ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀, tí ó gbin ọgbà àjàrà.
21. Noa mu àmupara ninu ọtí waini ọgbà rẹ̀, ó sì sùn sinu àgọ́ rẹ̀ ní ìhòòhò.
22. Hamu, baba Kenaani, rí baba rẹ̀ ní ìhòòhò, ó lọ sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ mejeeji lóde.