Jẹnẹsisi 9:14-29 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Nígbàkúùgbà tí mo bá mú kí òjò ṣú ní ojú ọ̀run, tí òṣùmàrè bá sì yọ jáde,

15. n óo ranti majẹmu tí mo bá ẹ̀yin ati gbogbo ẹ̀dá alààyè dá pé, omi kò ní kún débi pé yóo pa ayé rẹ́ mọ́.

16. Nígbà tí òṣùmàrè bá yọ, n óo wò ó, n óo sì ranti majẹmu ayérayé tí èmi Ọlọrun bá gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà láyé dá.

17. Èyí ni majẹmu tí mo bá gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà láyé dá.”

18. Àwọn ọmọ Noa tí wọ́n jáde ninu ọkọ̀ ni: Ṣemu, Hamu ati Jafẹti. Hamu ni ó bí Kenaani.

19. Àwọn ọmọ Noa mẹtẹẹta yìí ni baba ńlá gbogbo ayé.

20. Noa ni ẹni kinni tí ó kọ́kọ́ ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀, tí ó gbin ọgbà àjàrà.

21. Noa mu àmupara ninu ọtí waini ọgbà rẹ̀, ó sì sùn sinu àgọ́ rẹ̀ ní ìhòòhò.

22. Hamu, baba Kenaani, rí baba rẹ̀ ní ìhòòhò, ó lọ sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ mejeeji lóde.

23. Ṣemu ati Jafẹti bá mú aṣọ kan, wọ́n fà á kọ́ èjìká wọn, wọ́n fi ẹ̀yìn rìn lọ sí ibi tí baba wọn sùn sí, wọ́n sì dà á bò ó, wọ́n kọ ojú sí ẹ̀gbẹ́ kan, wọn kò sì rí ìhòòhò baba wọn.

24. Nígbà tí ọtí dá lójú Noa, tí ó gbọ́ ohun tí àbíkẹ́yìn rẹ̀ ṣe sí i,

25. Ó ní,“Ẹni ègún ni Kenaani,ẹrú lásánlàsàn ni yóo jẹ́ fún àwọn arakunrin rẹ̀.”

26. Ó tún fi kún un pé,“Kí OLUWA Ọlọrun mi bukun Ṣemu,ẹrú rẹ̀ ni Kenaani yóo máa ṣe.

27. Kí Ọlọrun sọ ìdílé Jafẹti di pupọ,kí ó máa gbé ninu àgọ́ Ṣemu,ẹrú rẹ̀ ni Kenaani yóo máa ṣe.”

28. Ọọdunrun ọdún ó lé aadọta (350) ni Noa tún gbé sí i lẹ́yìn ìkún omi.

29. Noa kú nígbà tí ó di ẹni ẹgbẹrun ọdún ó dín aadọta (950).

Jẹnẹsisi 9