Jẹnẹsisi 8:3-13 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Omi bá bẹ̀rẹ̀ sí fà lórí ilẹ̀. Lẹ́yìn aadọjọ (150) ọjọ́, omi náà fà tán.

4. Ní ọjọ́ kẹtadinlogun oṣù keje, ìdí ọkọ̀ náà kanlẹ̀ lórí òkè Ararati.

5. Omi náà sì ń fà sí i títí di oṣù kẹwaa. Ní ọjọ́ kinni oṣù náà ni ṣóńṣó orí àwọn òkè ńlá hàn síta.

6. Lẹ́yìn ogoji ọjọ́, Noa ṣí fèrèsé ọkọ̀ tí ó kàn.

7. Ó rán ẹyẹ ìwò kan jáde. Ẹyẹ yìí bẹ̀rẹ̀ sí fò káàkiri títí tí omi fi gbẹ lórí ilẹ̀.

8. Ó tún rán ẹyẹ àdàbà kan jáde láti lọ wò ó bóyá omi ti gbẹ lórí ilẹ̀,

9. ṣugbọn àdàbà náà kò rí ibi tí ó lè bà sí nítorí pé omi bo gbogbo ilẹ̀, ó bá fò pada tọ Noa lọ ninu ọkọ̀. Noa na ọwọ́ jáde láti inú ọkọ̀, ó sì mú un wọlé.

10. Ó dúró fún ọjọ́ meje kí ó tó tún rán àdàbà náà jáde.

11. Àdàbà náà fò pada ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà pẹlu ewé olifi tútù ní ẹnu rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Noa ṣe mọ̀ pé omi ti fà lórí ilẹ̀.

12. Ó tún dúró fún ọjọ́ meje sí i, lẹ́yìn náà, ó tún rán àdàbà náà jáde, ṣugbọn àdàbà náà kò pada sọ́dọ̀ Noa mọ́.

13. Ní ọjọ́ kinni oṣù kinni ọdún tí Noa di ẹni ọdún mọkanlelẹgbẹta (601), omi gbẹ tán lórí ilẹ̀. Noa ṣí òrùlé ọkọ̀, ó yọjú wo ìta, ó sì rí i pé ilẹ̀ ti gbẹ.

Jẹnẹsisi 8