Jẹnẹsisi 34:13-15 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Ọgbọ́n ẹ̀tàn ni àwọn ọmọ Jakọbu fi dá Ṣekemu ati Hamori, baba rẹ̀ lóhùn, nítorí bíbà tí ó ba Dina, arabinrin wọn jẹ́.

14. Wọ́n wí fún wọn pé, “Ìtìjú gbáà ni ó jẹ́, pé kí a fi ọmọbinrin wa fún ẹni tí kò kọlà abẹ́, a kò gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ rárá.

15. Ohun kan ṣoṣo tí ó lè mú kí ọ̀rọ̀ náà ṣeéṣe ni pé kí ẹ̀yin náà dàbí wa, kí gbogbo ọkunrin yín kọlà abẹ́.

Jẹnẹsisi 34