Jẹnẹsisi 25:28-31 BIBELI MIMỌ (BM)

28. Isaaki fẹ́ràn Esau nítorí ẹran ìgbẹ́ tí ó máa ń fún un jẹ nígbà gbogbo, ṣugbọn Jakọbu ni Rebeka fẹ́ràn.

29. Ní ọjọ́ kan, bí Jakọbu ti ń se ẹ̀bẹ lọ́wọ́ ni Esau ti oko ọdẹ dé, ebi sì ti fẹ́rẹ̀ pa á kú.

30. Esau sọ fún Jakọbu pé, “Jọ̀wọ́ fún mi jẹ ninu ẹ̀bẹ tí ó pupa yìí nítorí pé ebi ń pa mí kú lọ.” (Nítorí ọ̀rọ̀ yìí ni wọ́n ṣe ń pè é ní Edomu.)

31. Jakọbu bá dáhùn pé, “Kọ́kọ́ gbé ipò àgbà rẹ fún mi ná.”

Jẹnẹsisi 25