1. Èmi Jakọbu, iranṣẹ Ọlọrun, ati ti Oluwa wa, Jesu Kristi, ni ó ń kọ ìwé yìí sí àwọn ẹ̀yà mejila tí ó fọ́nká gbogbo ayé. Alaafia fun yín!
2. Ẹ̀yin ará mi, ẹ kà á sí ayọ̀ gidi nígbà tí oríṣìíríṣìí ìdánwò bá dé ba yín.
3. Kí ẹ mọ̀ pé ìdánwò igbagbọ yín ń mú kí ẹ ní ìfaradà.
4. Ẹ níláti ní ìfaradà títí dé òpin, kí ẹ lè di pípé, kí ẹ sì ní ohun gbogbo lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, láìsí ìkùnà kankan.
5. Bí ẹnikẹ́ni bá wà ninu yín, tí ọgbọ́n kù díẹ̀ kí ó tó fún, kí olúwarẹ̀ bèèrè lọ́dọ̀ Ọlọrun, yóo sì fún un. Nítorí Ọlọrun lawọ́, kì í sìí sìrègún.
6. Ṣugbọn olúwarẹ̀ níláti bèèrè pẹlu igbagbọ, láì ṣiyèméjì. Nítorí ẹni tí ó bá ń ṣiyèméjì dàbí ìgbì omi òkun, tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri tí ó sì ń rú sókè.
9. Kí arakunrin tí ó jẹ́ mẹ̀kúnnù kí ó yọ̀ nígbà tí Ọlọrun bá gbé e ga.
10. Bẹ́ẹ̀ ni kí ọlọ́rọ̀ kí ó yọ̀ nígbà tí Ọlọrun bá rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀, nítorí bí òdòdó koríko ìgbẹ́ ni ọlọ́rọ̀ kò ní sí mọ́.