1. OLUWA ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, mú idà kan tí ó bá mú, lò ó gẹ́gẹ́ bí abẹ ìfárí, kí o fi fá orí ati irùngbọ̀n rẹ. Mú òṣùnwọ̀n tí a fi ń wọn nǹkan kí o fi pín irun tí o bá fá sí ọ̀nà mẹta.
2. Jó ìdámẹ́ta rẹ̀ ninu iná láàrin ìlú, ní ìgbà tí ọjọ́ tí a fi dóti ìlú náà bá parí. Máa fi idà gé ìdámẹ́ta, kí o sì fọ́n ọn káàkiri lẹ́yìn ìlú, fọ́n ìdámẹ́ta yòókù káàkiri sinu afẹ́fẹ́, n óo sì fa idà yọ tẹ̀lé e.
3. Mú díẹ̀ ninu irun náà kí o dì í sí etí ẹ̀wù rẹ.
4. Mú díẹ̀ ninu èyí tí o dì sí etí ẹ̀wù, jù ú sinu iná kí ó jóná; iná yóo sì ti ibẹ̀ ṣẹ́ sí gbogbo ilé Israẹli.”
5. OLUWA Ọlọrun ní: “Jerusalẹmu nìyí. Mo ti fi í sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, mo sì ti fi àwọn agbègbè yí i ká.
6. Ó ti tàpá sí òfin mi ju àwọn orílẹ̀-èdè yòókù lọ, ó sì ti kọ ìlànà mi sílẹ̀ ju àwọn agbègbè tí ó yí i ká lọ. Wọ́n kọ òfin mi sílẹ̀, wọn kò sì tẹ̀lé ìlànà mi.
7. Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun ní nítorí pé rúdurùdu yín ju ti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí i yín ká lọ, ati pé ẹ kò tẹ̀lé ìlànà mi, ẹ kò sì pa òfin mi mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀ ń tẹ̀lé ìlànà àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí i yín ká.
8. Nítorí náà, èmi, OLUWA Ọlọrun fúnra mi, ni mo dójú le yín, n óo sì ṣe ìdájọ́ fun yín lójú àwọn orílẹ̀-èdè.
9. Nítorí gbogbo ìwà ìríra yín, n óo ṣe ohun tí n kò ṣe rí si yín, tí n kò sì ní ṣe irú rẹ̀ mọ́ lae.