Isikiẹli 47:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọkunrin náà bá mú mi pada wá sí ẹnu ọ̀nà Tẹmpili, mo sì rí i tí omi kan ń sun láti abẹ́ ìlẹ̀kùn àbájáde ó ń ṣàn lọ sí ìhà ìlà oòrùn, ìhà ìlà oòrùn ni tẹmpili kọjú sí. Omi náà ń ṣàn láti apá gúsù ibi ìlẹ̀kùn àbájáde tí ó wà ni ìhà gúsù pẹpẹ ìrúbọ.

2. Lẹ́yìn náà ó mú mi gba ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá jáde, ó sì mú mi yípo ní ìta títí tí mo fi dé ẹnu ọ̀nà àbájáde tí ó kọjú sí ìlà oòrùn. Odò kékeré kan ń ṣàn jáde láti ìhà gúsù.

3. Ọkunrin náà lọ sí apá ìhà ìlà oòrùn, ó mú okùn ìwọ̀n kan lọ́wọ́. Ó fi wọn ẹgbẹrun igbọnwọ, (mita 450). Ó sì mú mi la odò kan tí ó mù mí dé kókósẹ̀ kọjá.

4. Ó tún wọn ẹgbẹrun igbọnwọ (mita 450) mìíràn sí ìsàlẹ̀, ó sì mú mi la odò náà kọjá: odò yìí sì mù mí dé orúnkún. Ọkunrin náà tún wọn ẹgbẹrun igbọnwọ (mita 450) mìíràn sí ìsàlẹ̀, ó tún mú mi la odò náà kọjá: ó sì mù mí dé ìbàdí.

5. Nígbà tí ó yá, ó tún wọn ẹgbẹrun igbọnwọ (mita 450), mìíràn sí ìsàlẹ̀, odò náà jìn ju ohun tí mo lè là kọjá lọ, nítorí pé ó ti kún sí i, ó jìn tó ohun tí eniyan lè lúwẹ̀ẹ́ ninu rẹ̀. Ó kọjá ohun tí eniyan lè là kọjá.

6. Ọkunrin náà bá sọ fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, ṣé o rí nǹkan?” Nígbà náà ni ó mú mi gba etí odò náà pada.

7. Bí mo ṣe ń pada bọ̀, mo rí ọpọlọpọ igi ní bèbè kinni keji odò náà.

8. Ó ní, “Omi yìí ń ṣàn lọ sí Araba, ní ìhà ìlà oòrùn, nígbà tí ó bá sì ṣàn wọ inú òkun, omi inú òkun, yóo di omi tí ó mọ́ gaara.

9. Ọpọlọpọ ohun ẹlẹ́mìí yóo wà ní ibikíbi tí omi náà bá ti ṣàn kọjá. Ẹja yóo pọ̀ ninu rẹ̀; nítorí pé omi yìí ṣàn lọ sí inú òkun, omi tí ó wà níbẹ̀ yóo di mímọ́ gaara, ohunkohun tí ó bá sì wà ní ibi tí odò yìí bá ti ṣàn kọjá yóo yè.

10. Àwọn apẹja yóo dúró létí òkun láti Engedi títí dé Enegilaimu, ibẹ̀ yóo di ibi tí wọn yóo ti máa na àwọ̀n wọn sá sí. Oríṣìíríṣìí ẹja ni yóo wà níbẹ̀ bí ẹja inú Òkun Ńlá.

11. Ṣugbọn ibi ẹrọ̀fọ̀ ati àbàtà rẹ̀ kò ní di mímọ́ gaara, iyọ̀ ni yóo wà níbẹ̀.

Isikiẹli 47