18. OLUWA Ọlọrun ní, “Ní ọjọ́ kinni oṣù kinni, ẹ pa ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan tí kò ní àbààwọ́n, kí ẹ fi ṣe ìwẹ̀nùmọ́ ibi mímọ́.
19. Alufaa yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, yóo fi sí ara òpó ìlẹ̀kùn tẹmpili, ati orígun mẹrẹẹrin pẹpẹ ati òpó ìlẹ̀kùn àbáwọlé gbọ̀ngàn ààrin ilé.
20. Bákan náà ni ẹ gbọdọ̀ ṣe ní ọjọ́ keje oṣù láti ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀; kí ẹ lè ṣe ètùtù fún tẹmpili.
21. “Ní ọjọ́ kẹrinla oṣù kinni, ẹ gbọdọ̀ ṣe ọdún Àjọ Ìrékọjá, burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ni ẹ óo máa jẹ fún ọjọ́ meje.
22. Ní ọjọ́ náà ọba yóo pa ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀ ati fún gbogbo àwọn ará ìlú.
23. Fún ọjọ́ meje tí ẹ óo fi ṣe àjọ̀dún yìí, yóo mú ọ̀dọ́ akọ mààlúù meje ati àgbò meje tí kò ní àbààwọ́n wá fún ẹbọ sísun, ati òbúkọ kọ̀ọ̀kan fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.