18. Wọn yóo wé lawani tí a fi aṣọ funfun rán, wọn yóo sì wọ ṣòkòtò aṣọ funfun. Wọn kò gbọdọ̀ fi ohunkohun tí ń mú kí ooru mú eniyan di ara wọn ní àmùrè.
19. Nígbà tí wọ́n bá fẹ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan ní gbọ̀ngàn ìta, wọn yóo bọ́ aṣọ tí wọ́n wọ̀ nígbà tí wọn ń ṣiṣẹ́ iranṣẹ sí àwọn yàrá mímọ́. Wọn yóo wọ aṣọ mìíràn kí wọn má baà sọ àwọn eniyan náà di mímọ́ nítorí ẹ̀wù wọn.
20. “Wọn kò gbọdọ̀ fá irun orí wọn tabi kí wọn jẹ́ kí oko irun wọn gùn, wọn yóo máa gé díẹ̀díẹ̀ lára irun orí wọn ni.
21. Kò sí alufaa kan tí ó gbọdọ̀ mu ọtí waini nígbà tí ó bá wọ gbọ̀ngàn inú.
22. Wọn kò gbọdọ̀ fẹ́ opó tabi obinrin tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀, àfi wundia tí kò tíì mọ ọkunrin láàrin àwọn eniyan Israẹli tabi opó tí ó jẹ́ aya alufaa.