29. Bákan náà sì ni àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àtẹ́rígbà rẹ̀ ati ìloro rẹ̀ pẹlu àwọn yòókù. Fèrèsé wà lára rẹ̀ yíká ninu, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìloro rẹ̀. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½).
30. Àwọn ìloro wà yí i ká, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gùn ní igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½), wọ́n sì fẹ̀ ní igbọnwọ marun-un (mita 2½).
31. Ìloro rẹ̀ kọjú sí gbọ̀ngàn òde, àwòrán ọ̀pẹ wà lára àtẹ́rígbà rẹ̀, àtẹ̀gùn rẹ̀ sì ní ìgbésẹ̀ mẹjọ.
32. Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí ìhà ìlà oòrùn gbọ̀ngàn inú, ó sì wọn ẹnu ọ̀nà rẹ̀, bákan náà ni ó rí pẹlu àwọn yòókù.
33. Bákan náà sì ni àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, ati àtẹ́rígbà, ati ìloro rẹ̀ rí pẹlu àwọn yòókù, fèrèsé wà lára òun náà yíká ninu, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìloro rẹ̀. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½).
34. Ìloro rẹ̀ kọjú sí gbọ̀ngàn òde, àwòrán ọ̀pẹ wà lára àtẹ́rígbà rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji, àtẹ̀gùn rẹ̀ sì ní ìgbésẹ̀ mẹjọ.
35. Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí ibi ẹnu ọ̀nà tí ó wà ní ìhà àríwá, ó sì wọ̀n ọ́n, bákan náà ni òun náà rí pẹlu àwọn yòókù.
36. Bákan náà ni àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àtẹ́rígbà rẹ̀ ati ìloro rẹ̀ rí pẹlu àwọn yòókù, ó sì ní fèrèsé yíká. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½).
37. Ìloro rẹ̀ kọjú sí gbọ̀ngàn òde, àwòrán ọ̀pẹ wà lára àtẹ́rígbà rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji, àtẹ̀gùn rẹ̀ sì ní ìgbésẹ̀ mẹjọ.
38. Yàrá kan wà tí ìlẹ̀kùn rẹ̀ wà ninu ìloro ẹnu ọ̀nà, níbẹ̀ ni wọ́n tí ń fọ ẹran tí wọ́n bá fẹ́ fi rú ẹbọ sísun.