21. Àwọn yàrá mẹta mẹta wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji. Àtẹ́rígbà ati ìloro rẹ̀ rí bákan náà pẹlu àwọn ti ẹnu ọ̀nà àkọ́kọ́. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ, (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½).
22. Àwọn fèrèsé rẹ̀, ati ìloro rẹ̀ ati àwọn àwòrán ọ̀pẹ ara rẹ̀ rí bíi àwọn ti ẹnu ọ̀nà tí ó kọjú sí ìlà oòrùn. Ó ní àtẹ̀gùn meje, ìloro rẹ̀ sì wà ninu.
23. Níwájú ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá, ni ẹnu ọ̀nà gbọ̀ngàn inú wà bí ó ti wà níwájú ẹnu ọ̀nà ti ìlà oòrùn. Ọkunrin náà wọn ibẹ̀ láti ẹnu ọ̀nà kan sí ikeji, ó jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45).
24. Ó mú mi lọ sí apá ìhà gúsù, mo sì rí ẹnu ọ̀nà kan níbẹ̀. Ó wọn àtẹ́rígbà ati ìloro rẹ̀, wọ́n sì rí bákan náà pẹlu àwọn yòókù.
25. Fèrèsé yí inú ati ìloro rẹ̀ ká, bíi àwọn fèrèsé ti àwọn ẹnu ọ̀nà yòókù. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½).
26. Ó ní àtẹ̀gùn meje, ìloro rẹ̀ wà ninu, àwòrán ọ̀pẹ sì wà lára àtẹ́rígbà rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji.
27. Ẹnu ọ̀nà kan wà ní ìhà gúsù gbọ̀ngàn inú. Ó wọn ibẹ̀, láti ẹnu ọ̀nà náà sí ẹnu ọ̀nà tí ó wà ní ìhà gúsù, jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45).