Isikiẹli 39:26-29 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Wọn yóo gbàgbé ìtìjú wọn ati ìwà ọ̀tẹ̀ tí wọn hù sí mi, nígbà tí wọn bá ń gbé orí ilẹ̀ wọn láìléwu, tí kò sì sí ẹni tí yóo dẹ́rùbà wọ́n.

27. Nígbà tí mo bá kó wọn pada láti inú oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè, tí mo kó wọn jọ láti ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn, n óo fi ara mi hàn bí ẹni mímọ́ lójú ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè.

28. Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn, nítorí pé mo kó wọn lọ sí ìgbèkùn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, mo sì tún kó wọn pada sí ilẹ̀ wọn. N kò ní fi ọ̀kankan ninu wọn sílẹ̀ sí ààrin orílẹ̀-èdè mìíràn mọ́.

29. N óo tú ẹ̀mí mi lé àwọn ọmọ Israẹli lórí, n ko ní gbé ojú mi kúrò lọ́dọ̀ wọn mọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Isikiẹli 39