10. “ ‘Nítorí ẹ̀yin ará Edomu sọ pé, àwọn orílẹ̀-èdè mejeeji wọnyi ati ilẹ̀ wọn yóo di tiyín ati pé ẹ óo jogún rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA wà níbẹ̀.
11. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, mo fi ara mi búra, bí ẹ ti fi ìrúnú ati owú ṣe sí wọn nítorí pé ẹ kórìíra wọn, bẹ́ẹ̀ gan-an ni èmi náà óo ṣe sí ọ; n óo sì jẹ́ kí ẹ mọ irú ẹni tí mo jẹ́ nígbà tí mo bá dájọ́ fun yín.
12. Ẹ óo mọ̀ pé èmi OLUWA gbọ́ gbogbo ohun tí ẹ̀ ń sọ sí àwọn òkè Israẹli, pé wọ́n ti di ahoro ati ìkógun fun yín.
13. Ẹ̀ ń fi ẹnu yín sọ̀rọ̀ ìgbéraga sí mi, ẹ sì ń dá àpárá lù mí; gbogbo rẹ̀ ni mo gbọ́.’ ”
14. OLUWA Ọlọrun ní, “N óo sọ ìwọ Edomu di ahoro, kí gbogbo ayé lè yọ̀ ọ́;
15. bí o ti yọ ilẹ̀ Israẹli nígbà tí ilé wọn di ahoro. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe sí ọ, ìwọ náà óo di ahoro. Gbogbo òkè Seiri ati gbogbo ilẹ̀ Edomu yóo di ahoro. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”