1. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,
2. “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ kí o fi bá àwọn olùṣọ́-aguntan Israẹli wí, fi àsọtẹ́lẹ̀ bá àwọn olórí Israẹli wí pé, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Háà, ẹ̀yin olórí Israẹli tí ẹ̀ ń wá oúnjẹ fún ara yín, ṣé kò yẹ kí olùṣọ́-aguntan máa pèsè oúnjẹ fún àwọn aguntan rẹ̀?
3. Ẹ̀yin ń jẹ ẹran ọlọ́ràá, ẹ̀ ń fi irun aguntan bo ara yín, ẹ̀ ń pa aguntan tí ó sanra jẹ; ṣugbọn ẹ kò fún àwọn aguntan ní oúnjẹ.
4. Ẹ kò tọ́jú àwọn tí wọn kò lágbára, ẹ kò tọ́jú àwọn tí ń ṣàìsàn, ẹ kò tọ́jú ẹsẹ̀ àwọn tí wọn dá lẹ́sẹ̀, ẹ kò mú àwọn tí wọn ń ṣáko lọ pada wálé; ẹ kò sì wá àwọn tí wọ́n sọnù. Pẹlu ipá ati ọwọ́-líle ni ẹ fi ń ṣe àkóso wọn.
5. Nítorí náà, wọ́n túká nítorí pé wọn kò ní olùṣọ́, wọ́n sì di ìjẹ fún àwọn ẹranko burúkú.