29. Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá sọ ilẹ̀ náà di ahoro ati aṣálẹ̀, nítorí gbogbo ìwà ìríra tí wọ́n ti hù.
30. “Ní tìrẹ, ìwọ ọmọ eniyan, àwọn eniyan rẹ tí ń sọ̀rọ̀ rẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri ati lẹ́nu ọ̀nà àbáwọlé wọn, wọ́n ń wí fún ara wọn pé: ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ gbọ́ ohun tí OLUWA wí.’
31. Wọ́n ń wá sọ́dọ̀ rẹ bí àwọn eniyan tií wá, wọ́n sì ń jókòó níwájú rẹ bí eniyan mi. Wọ́n ń gbọ́ ohun tí ò ń wí, ṣugbọn wọn kò ní ṣe é; nítorí pé ẹnu lásán ni wọ́n fi ń sọ pé wọ́n ní ìfẹ́ pupọ, ṣugbọn níbi èrè tí wọn ó jẹ ni ọkàn wọn wà.
32. Lójú wọn, o dàbí olóhùn iyọ̀ tí ń kọrin ìfẹ́, tí ó sì mọ ohun èlò orin lò dáradára. Wọ́n ń gbọ́ ohun tí ò ń wí, ṣugbọn wọn kò ní ṣe é.
33. Ṣugbọn nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ, (bẹ́ẹ̀ yóo sì ṣẹ), wọn óo wá mọ̀ pé wolii kan wà láàrin wọn.”