1. Ní ọjọ́ kinni, oṣù kẹta, ọdún kọkanla tí a ti wà ní ìgbèkùn, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,
2. “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún Farao, ọba Ijipti, pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ pé,Ta ni ó lágbára tó ọ?
3. Wò ó! Mo fi ọ́ wé igi kedari Lẹbanoni,àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lẹ́wà,wọ́n sì ní ìbòòji ó ga fíofío,orí rẹ̀ sì kan ìkùukùu lójú ọ̀run.
4. Omi mú kí ó dàgbà,ibú omi sì mú kí ó ga.Ó ń mú kí àwọn odò rẹ̀ ṣàn yí ibi tí a gbìn ín sí ká.Ó ń mú kí odò rẹ̀ ṣàn lọ síbi gbogbo igi igbó.
5. Nítorí náà, ó ga sókè fíofío, ju gbogbo igi inú igbó lọ.Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tóbi, wọ́n sì gùn,nítorí ọpọlọpọ omi tí ó ń rí.
6. Gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run, pa ìtẹ́ sára àwọn ẹ̀ka rẹ̀.Lábẹ́ rẹ̀ ni gbogbo ẹranko inú igbó ń bímọ sí.Gbogbo orílẹ̀-èdè ńláńlá sì fi ìbòòji abẹ́ rẹ̀ ṣe ibùgbé.
7. Ó tóbi, ó lọ́lá ẹ̀ka rẹ̀ sì lẹ́wànítorí pé gbòǹgbò rẹ̀ wọ ilẹ̀ lọ,ó sì kan ọpọlọpọ omi nísàlẹ̀ ilẹ̀.
8. Igi kedari tí ó wà ninu ọgbà Ọlọrun kò lè farawé e.Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ka igi firi kò sì tó ẹ̀ka rẹ̀.Ẹ̀ka igi kankan kò dàbí ẹ̀ka rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò sí igikígi ninu ọgbà Ọlọrun tí ó lẹ́wà bíi rẹ̀.
9. Mo dá a ní arẹwà, pẹlu ẹ̀ka tí ó pọ̀.Gbogbo igi ọgbà Edẹni,tí ó wà ninu ọgbà Ọlọrun sì ń jowú rẹ̀.
10. “Nítorí pé ó ga sókè fíofío, góńgó orí rẹ̀ wọ inú ìkùukùu lójú ọ̀run, ọkàn rẹ̀ sì kún fún ìgbéraga nítorí gíga rẹ̀.