6. OLUWA ní, “Àwọn tí ń ran Ijipti lọ́wọ́ yóo ṣubú,ìgbéraga rẹ̀ yóo sì wálẹ̀;láti Migidoli títí dé Siene,wọn ó kú ikú ogun láàrin ìlú.Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
7. “Ijipti óo di ahoro patapata àwọn ìlú rẹ̀ yóo wà lára àwọn ìlú tí yóo tú patapata.
8. Wọn yóo mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá dáná sun Ijipti, tí gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ bá ṣubú.
9. “Nígbà tó bá tó àkókò, n óo rán àwọn ikọ̀ ninu ọkọ̀ ojú omi, wọn ó lọ dẹ́rù ba àwọn ará Etiopia tí wọn ń gbé láìfura. Wahala yóo dé bá àwọn ará Etiopia ní ọjọ́ ìparun Ijipti. Wò ó, ìparun náà ti dé tán.”
10. OLUWA Ọlọrun ní, “N óo ti ọwọ́ Nebukadinesari, ọba Babiloni, fi òpin sí ọrọ̀ Ijipti.
11. Òun ati àwọn eniyan rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè oníjàgídíjàgan jùlọ ni, yóo wá pa ilẹ̀ Ijipti run, wọn yóo yọ idà ti Ijipti, ọpọlọpọ yóo sì kú ní ilẹ̀ náà.