Isikiẹli 30:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

2. “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ kí o sì wí pé, OLUWA Ọlọrun ní,

3. ‘Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn nítorí ọjọ́ burúkú tí ń bọ̀,nítorí ọjọ́ náà súnmọ́lé,ọjọ́ OLUWA ti dé tán,yóo jẹ́ ọjọ́ ìṣúduduati ìparun fún àwọn orílẹ̀-èdè.

4. Ogun yóo jà ní Ijipti,ìrora yóo sì bá Etiopia.Nígbà tí ọpọlọpọ òkú bá sùn ní Ijipti,tí a kó ọrọ̀ rẹ̀ lọ,tí a sì wó ìpìlẹ̀ rẹ̀ lulẹ̀.

5. “ ‘Àwọn ará Etiopia, ati Puti, ati Ludi, ati gbogbo ilẹ̀ Arabia ati Libia, ati gbogbo àwọn eniyan wa tí wọ́n jọ gbìmọ̀ pọ̀, ni ogun yóo pa.’ ”

6. OLUWA ní, “Àwọn tí ń ran Ijipti lọ́wọ́ yóo ṣubú,ìgbéraga rẹ̀ yóo sì wálẹ̀;láti Migidoli títí dé Siene,wọn ó kú ikú ogun láàrin ìlú.Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

7. “Ijipti óo di ahoro patapata àwọn ìlú rẹ̀ yóo wà lára àwọn ìlú tí yóo tú patapata.

Isikiẹli 30