8. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní: “Wò ó, n óo fi ogun jà yín, n óo sì pa yín run, ati eniyan ati ẹranko.
9. Ilẹ̀ Ijipti yóo di ahoro, yóo sì di aṣálẹ̀. Wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.“Nítorí o wí pé, ‘Èmi ni mo ni odò Naili, ara mi ni mo dá a fún,’
10. nítorí náà, mo lòdì sí ìwọ ati àwọn odò rẹ, n óo sì sọ ilẹ̀ Ijipti di ahoro ati aṣálẹ̀ patapata láti Migidoli dé Siene, títí dé ààlà Etiopia.
11. Eniyan tabi ẹranko kò ní gba ibẹ̀ kọjá, ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀ fún ogoji ọdún.
12. N óo sọ ilẹ̀ Ijipti di ahoro patapata, n óo jẹ́ kí àwọn ìlú rẹ̀ di ahoro fún ogoji ọdún. N óo fọ́n àwọn ará Ijipti káàkiri gbogbo ayé, n óo sì tú wọn ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.”