1. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,
2. “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún ọba Tire pé OLUWA ní, ‘Nítorí pé ìgbéraga kún ọkàn rẹ, o sì ti sọ ara rẹ di oriṣa, o sọ pé o jókòó ní ibùjókòó àwọn oriṣa láàrin òkun; bẹ́ẹ̀ sì ni eniyan ni ọ́, o kì í ṣe oriṣa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ò ń rò pé o gbọ́n bí àwọn oriṣa,
3. nítòótọ́, o gbọ́n ju Daniẹli lọ, kò sì sí ohun àṣírí kan tí ó ṣú ọ lójú.
4. Nípa ọgbọ́n ati ìmọ̀ rẹ, o ti kó ọpọlọpọ ọrọ̀ jọ fún ara rẹ, o sì kó wúrà ati fadaka jọ sinu ilé ìṣúra rẹ.
5. O ti ní àníkún ọrọ̀ nítorí ọgbọ́n rẹ ninu òwò ṣíṣe, ìgbéraga sì ti kún ọkàn rẹ nítorí ọrọ̀ rẹ.’
6. “Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Nítorí pé o ka ara rẹ kún ọlọ́gbọ́n bí àwọn oriṣa,
7. n óo kó àwọn àjèjì wá bá ọ; àwọn tí wọ́n burú jù ninu àwọn orílẹ̀-èdè, wọn óo sì gbógun tì ọ́, wọ́n yóo sì ba ẹwà ati ògo rẹ jẹ́, pẹlu ọgbọ́n rẹ.
8. Wọn óo tì ọ́ sinu ọ̀gbun; o óo sì kú ikú ogun láàrin omi òkun.
9. Ṣé o óo lè sọ pé oriṣa kan ni ọ́ lójú àwọn tí wọ́n bá fẹ́ pa ọ́? Nígbà tí wọ́n bá ń ṣá ọ lọ́gbẹ́, ṣé eniyan ni o óo wá pe ara rẹ àbí oriṣa.