31. Wọn óo fá irun orí wọn nítorí rẹ,wọn óo sán aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ìdí,wọn óo sì fi ìbànújẹ́ ọkàn sọkún nítorí rẹ,inú wọn yóo sì bàjẹ́.
32. Bí wọ́n bá ti ń sọkún,wọn óo máa kọ orin arò nípa rẹ báyìí pé:‘Ìlú wo ló tíì parun bíi Tire, láàrin òkun?
33. Nígbà tí àwọn ọjà rẹ bá dé láti òkè òkun,ò ń tẹ́ ọpọlọpọ eniyan lọ́rùn.Ò ń fi ọpọlọpọ ọrọ̀ rẹ ati ọjà rẹsọ àwọn ọba ayé di ọlọ́rọ̀.
34. Wàyí ò, omi òkun ti fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́,o ti rì sí ìsàlẹ̀ òkun.’Gbogbo àwọn ọjà rẹati àwọn tí ń wa ọkọ̀ rẹ ti rì pẹlu rẹ.